Atelewo
Ore wa,
won ni agba ti n sare ninu eekan,
bi o ba si nkan ti n le,
aa si ni nkan ti n le.
K'orisa oke maa je ki riri wa o po ju
airi lo,
mo maa wa tun de loni,
emi ni Alabi oko Abebi,
emi ni Ikoyi eru ofa,
tapotapo e si n d'eru oogun ba'ni,
Onikoyi o — se kosi nkan?
Oogun lo buru l'eso o de'le pe,
Oogun lo buru l'eso o pe'ra won
loruko,
Onikoyi kii gb'ofa leyin,
gbagba iwaju ni baba won fi n gb'ota
o ri oun alumoni fi se'so,
Edumare to s'eda dudu oun pupa
sebi oun naa lo s'eda olowo ati
talaka,
o ni ki olowo maa l'owo si,
ki olosi maa we ninu odo ise,
mo wa ni se oun a ba lowo eni ni
tunmo igbesi aye eni ni?
B'o ba je be, tani oloola to ko'la Oba
Ogunwusi,
tani oloola to ko ti baba Ogunde,
Mo ni, tani oloola to ko ti
Owokoniran,
bee oloola yii kan na lo ko ti
Tanmola,
oun lo ko ti Kadara lowo,
oun naa lo ko ti Kashimawo.
Atelewo eni kii tan'ni je lo kuku wii
amo bi atelewo eni ba ko,
ti o gbe'ni de ibi ire,
bi a be atelewo oun so'nu,
se o l'eewo bi?
Kosi oun o buru nibe!
Ore wa,
atelewo la ba ila,
a o mo eni ti o ko,
iku ti n p'ode, mo sebi inu aapo ni n
gbe,
iku ti n p'omuwe, inu odo ni n f'orisi,
iku ti n p'akikanju, oju ogun ni n gbe
amo kini aditu eni lowo lolaa ati eni
ti
Ore mi atata,
ilu agidigbo l'oro yii,
ologbon ni n jo,
omoran ni n lu,
awon ara oke ohun ni si n tumo re
pelu,
ni o mu mi ranti ore mi — Dada
Awuru,
adahunse lo'ri owo lo gbe w'aaye,
won ni oun gan ni won o ba maa pe
l'olowo eyo,
bi o ba wa sise, yoo l'ola,
bi Dada ko, bi o sise, yoo l'ola,
abalo ababo, Dada o ri oun gbe'se ti o
fi re iwale aasa,
nje adiitu wa ko l'oro yii bi?
Aso maa l'edidi eniyan,
eniyan b'aso sile, bi obo laa ri,
opo eniyan aa si jo inaki,
a o ba ri eni ti ara re di koko
ati eni ti ara re se gbodidi,
Edumare, o maa ku'se o,
Oba nla ti n r'eru elegbo l'ese,
o ni ki esinsin fi maa r'oun s'ounje,
o ta elegbo l'ese, o k'owo, o ra.
Didikudi, Didikudi w’ole, ko gboran,
ti o fi gba iyi lodo oloko,
alawo ni ki o toju ewe eeya,
ki o toju ewe eegba,
won ni ooyun o m'oko ro,
nje ki won mu ooyun leyin orun,
o ni ariyaya n ti ya,
nje ki won na ni igi leyin orun,
o ni ewe eegba jo'gba,
mo wa ni, se atelewo lo gbe ooyun ni
abi ise owo eni?
Adiitu yii kuku ye oosa oke,
lo difa fun awon agba kan, agba kan
too ni Iyawo ti a fe l'ode ijo, eyin aro ni n sun
—
Abebi ti emi fe l'ode ijo,
o sun eyin aro o,
o n be n'iyewu ti n da'na ya mi lenu.
Awon agba kan, agba kan tii soro,
iba baba Faleti,
eyin l'eni Jogbo bi oro,
Jogbo bi oro,
oloju meji a se ise odo,
oloju meji a se ise Kaduna,
bi eyan o loju mejila, ko le se ilu Jogbo,
elenu meji a se Ibadan,
elenu meji a se Eko,
bi eyan o lenu mejidinlogun,
ko lee se ilu Jogbo
o ta Didikudi, o pa owo, o ra Agbari,
apa Agbari o r'oko, eyin Agbari o bere,
o tun ni fila aran l'oun fe maa de,
won ta, won fowo kowo, won ra Igunnu,
Igunnu d'oko, o feyin ti kukute, o n ye ara re
l'epon wo,
won ni eleyii o mo oko ro,
won ta, won f'owo kowo, won ra Tanndu,
oun na d'oko ko ri nkankan se,
won p'owo po, won le ra ooyun,
ooyun ni ki ni oun o maa se
olowo meji a se Ekiti,
olowo meji a se Egba,
bi eyan o l'owo merinlelogun,
ko le se ilu Jogbo,
Jogbo bi oro,
Jogbo ree bi Oro,
atelewo wa ni iwogbe wa,
Edumare so'ni l'oode aye,
ore mi atata, a o maa ri bi akuko ba tun ko,
ijakumo kii rin'de osan,
omo ree ki n rin'de oru.
Ire o.
Author: Yusuf Balogun Gemini
Post a Comment